Physical Attributes and Personalities

Can Do Statement

  • Describe people’s physical attributes, e.g height, complexion, personalities, etc.
  • Talk about different types of personalities.
  • Talk about what people wear and where they wear them.

Vocabulary List

Click the audio icon below to play the recorded pronunciation for each word. You can also open the list below in a new tab, which can be downloaded or printed.

Practice: Interpretive Communication

Presentational Communication

Context: Tolu is describing Barack Obama for the Yoruba class

 

Transcript:

Mo rí àrẹ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà tẹ́lẹ̀, Barack Obama, fún ìgbà àkọ́kọ́.  Barack Obámà ga tó ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà àti íǹṣì méjì. Wọn kò sanra rárá, wọ́n sì pupa díẹ̀. Barack Òbámà wọ súùtù dúdú, táì búlúù, àti ṣòkòtò gbọọrọ. Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú wọn wọ oríṣiríṣi súwẹ́tà àti kóòtù. Mo rò pé Barack Obama jẹ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn . Wọn kìí ṣe oníjàgídíjàgan rárá, wọ́n sì jẹ́ ènìyàn dáradára.

 

Practice: Presentational Communication

  • Read the transcript and write out words that express attributes and descriptions
  • Describe briefly your own attributes or personality

Interpersonal Communication

Context: Báyọ̀’s‘s friend has just joined the history class. Báyọ̀ is describing his friend to Tolú.

 

Transcript:

Báyọ̀: Ǹjẹ́ o pàdé Jòánù ní kíláàsì ìtàn lánàá?

Tolú: Rárá o. Tani Jòánù?

Báyọ̀: Jòánù jẹ́ ọ̀rẹ́ mi tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dara pọ̀ mọ́ kíláàsì ìtàn wa.

Tolú: Hm̀ḿm̀, mi ò (n kò) rò pé mo mọ Jòánù. Se àpèjúwe rẹ̀ fún mi.

Báyọ̀: Jòánù kò ga púpọ̀, kò ga ju ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà márùnún àti íǹsì mẹ́fà lọ. Ó mọ́ra díẹ̀, ó sì máa ń lo àwò ojú ní gbogbo ìgbà.

Tolú: Àbí Jòánù ni akẹ́kọ̀ọ́ tí  ó sọ̀rọ̀ púpọ̀ ní kíláàsì lánàá?

Báyọ̀: Ó tì o. Jòánù kìí sọ̀rọ̀ púpọ̀. Ó jẹ́ onísùúrù àti ènìyàn jẹ́jẹ́.

Tolú: Hmm, mo lérò pé màá rí Jòánù ní kíláàsì lọ́la.

Báyọ̀: Bẹ́ẹ̀ni. Pẹ̀lú gbogbo àpèjúwe mi yìí, o máa mọ̀ ọ́ tí o bá ri i.

Tolú: Kò burú.

 

Practice: Interpersonal Communication

  • Formulate a t least two sentences with descriptive words from the vocabulary list
  • Using the descriptive words you have learned, talk about your friend’s attributes. 

Grammar Notes

Adjectives or descriptive words

Adjectives are words that function as noun qualifiers in Yoruba. In Yoruba sentences, adjectives are used to describe or provide more information about a noun or nouns. Sometimes, words that are inherently adjectives in their categorization may function as verbs. This is because such words rely on the description to provide insights about the action of the subject (usually a noun) in the sentence.

Examples:

  1. Mo wọ aṣọ pupa. “I wear a red cloth.”

Note: Aṣọ “cloth,” is the noun, and pupa “red,” is the adjective, providing additional information about the cloth or simply describing the cloth that I wear.

  • Whereas, “pupa” can as well be used as a verb in a similar sentence, such as in example 2, below:

2. Asọ mi pupa. ” my cloth is red.”

3. Nígbà mìíràn, àwọn ọmọdé jẹ́ anìkànjọpọ́n. “Sometimes, children are selfish.”

  • “selfish and “red” in sentences 2 and 3 function as verbs .

Descriptive words or adjectives can be formulated from a verb.

Examples:

Gbọ́n “wise”→ọlọ́gbọ́n ” a wise person”

4. Túnde gbọn “Túndé is wise”

5. Túnde jẹ́ ọlọ́gbọ́n ” Túndé is a wise person.”

Ọlọ́gbọ́n as used in example 5 describes the type of person Túndé is.

License

Yorùbá Dictionary Copyright © 2024 by Adeola Agoke. All Rights Reserved.

Share This Book