Giving Directions
Can Do Statement
- Talking about where or places you want to go
- Asking questions to find your way around places
- Giving directions to people to locate buildings, places etc.
- Giving instructions about finding directions
Vocabulary List
Click the audio icon below to play the recorded pronunciation for each word. You can also open the list below in a new tab, which can be downloaded or printed.
Practice: Interpretive Communication
Presentational Communication
Context: Tolú explains how to give direction to a group of students.
Transcript:
Tí a bá fẹ́ júwe ọnà, a lẹ̀ lo máàpu gúgù, tàbí kí a ṣe àlàyé àpèjúwe ọ̀nà tí a máa rìn. Pẹ̀lú máàpù gúgù, a lè sọ orúkọ títì tí a máa dé, iye máìlì tí a máa rìn, àti orúkọ títì tí a ti máa yà. Nígbàmíràn, títì tí à ń júwe lè jẹ́ òpópónà márosẹ̀ tàbí ọ̀nà tóóró nínú àdúgbò. Ó ṣe pàtàkì láti mọ̀ bóyá apá ọ̀tún, àbí apá òsì, àbí tààrà ni a ti máa yà. Tí a kò bá fẹ́ lo máàpù gúgù, a lè ṣe àlàyé ọ̀nà fún ẹni tí ó bá bèèrè ọ̀nà. A gbọ́dọ̀ sọ iye ìṣẹ́jú tí ó máa rìn, ibi tí ó ti máa yà, àti àwọn nǹkan tí ó máa rí ní ojú ọnà.
Practice: Presentational Communication
- Bring out your google map
- Type your home address into google
- Use the appropriate vocabulary from the list to briefly describe direction from one point to the next
Interpersonal Communication
Context: Tóyìn is a new student at the University of Ibadan Nigeria. She asks Tọ́ba how to get to Agbowó from UI Campus, Nigeria.
Transcript:
Tóyìn: Ẹ kaàrọ̀ o. Ẹ jọ̀wọ́ báwo ni mo ṣe lè dé títì agbowo lati inú ọgbà UI?
Báyọ̀: Kò le rará. Tí o bá fẹ́ lọ sí títì Agbowo láti inú ọgbà Yunifásiti Ibàdàn, gba títì Awólọ́wọ̀ ti a wà lórí rẹ̀, lọ t̀aarà sí enu géètì UI.
Tóyìn Bii máìlì mélòó ni mo máa rin?
Báyọ̀: Kò pé ìlàjì máìlì. Sùgbọ́n o lè wọ bọ́ọ̀sì tí o bá fẹ.
Tóyìn: Ìlàjì máilì kò jìnà púpọ̀. Mo máa rìn.
Báyọ̀: Tí o bá dé ẹnu géètì, yà sí apá àláfíà, kí o máa lọ tààrà si apá ìsàlẹ̀ títì Agbowó.
Tóyìn: K̀o burú.
Báyọ̀: Lẹ́yìn náà, o máa rí àwọn oníṣòwò káràkátà ní apá ọ̀tún àti ní òsì. Títì agbowó nìyẹn.
Tóyìn Ó yé mi. Kò jinà rárá si géètì UI.
Báyọ̀: Kò jìnà rárá.
Tóyìn: Ẹ ṣeun.
Báyọ̀:: Ó dàbọ̀.
Practice: Interpersonal Communication
- Click on the video file and watch
- Make an attempt to do a similar role play with your classmate.
Grammar Notes
Homonyms
Homonyms are words that have the same letters and sounds but have different meanings. While meanings are generally constructed based on context of use, homonyms inherently have different meanings, and their use is expected to reflect the meaning(s) as used in sentences.
An example of a homonym used in this chapter is “fẹ́,” which has two distinct meanings: want or blow.
- T́adé fẹ́ ra iṣu díndín ní ilé oúnjẹ ” Tádé want to buy fried yam at the restaurant.”
- Fẹ́, in this context, simply expresses a desire or “want,” which functions as a helping verb in this sentence. In different contexts, “fẹ́” could have at least three other meanings.
2. In another context, “fẹ́” could have another meaning. For example, fẹ́, “to marry.” Olú fẹ́ Bọ́lá “Olú married Bọlá.”
3. Fẹ́, “blow,” e.g air. Mo lè fẹ́ atẹ́gùn sí àtùpà yìí. “I can blow some air at this lantern.
- Even though “fẹ́” is used differently in examples 1 to 3, “fẹ́” belongs in the verbal category of speech in Yoruba and conveys different meanings.