Means of Transportation and Future Plans

Can Do Statement

  • Talking about a trip and activities during a trip
  • Talking about different transportation systems
  • Talking about places and people you or others have (or have not) visited occasionally
  • Talking about a plan for the future

Vocabulary List

Click the audio icon below to play the recorded pronunciation for each word. You can also open the list below in a new tab, which can be downloaded or printed.

Practice: Interpretive Communication

Presentational Communication

Context: Tolú is talking about her travel plans for summer

 

Transcript:

Ní ṣọmà yìí, mo máa rin ìrìnajò lọ sí Miami ní Florida. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkọ̀ òfúrufú  ló rọrùn láti wọ̀, mo maá wa ọkọ̀ mi fún wákàtí méjìdínlógún  láti Wisconsin dé Miami, Florida. Tí mo bá dé Miami, mo máa ṣe oríṣirísi nǹkan. Mo máa gun kẹ̀kẹ́ mi láràárọ̀, mo máa pàdé àwọn ọ̀rẹ́ mi, a sì máa lọ sí oríṣiríṣi ilé oúnjẹ.

 

Practice: Presentational Communication

  • Click on the audio files and repeat the vocabulary for transportation
  • Write two sentences using the appropriate verb for the different means of transportation you have learned.

Interpersonal Communication

Context: Tóyìn and Tọ́ba are talking about transportation systems in the cities they live in.

 

Transcript:

Tóyìn : Ó yà mi lẹ́nu pé bọ́ọ̀sì ní ìlú Madison dàbí bọ́ọ̀sì ní ìlú Èkó ní Nàìjíríyà

Báyọ̀: Ìyẹn ni pé irú kan náà ni àwon bọ́ọ̀sì yìí.

Tóyìn: Bẹ́ẹ̀ni, ṣùgbọ́n a máa ń pe bọ́ọ̀sil ti ìlú Èkó ní BRT, Bus Rapid Transit System.

Báyọ̀: Ó yé mi. A kò fún àwọn bọ́ọ̀sì tí a ń lò ní ìlú Madison ní orúkọ kankan.

Tóyìn: Kódà, oríṣiríṣi bọ́ọ̀sì ni ó wà ní ìlú Èkó. A ní Dáńfó, Móòlù ẹ̀, BRT. A tún ní àwọn ọkọ̀ takisí oríṣiríṣi. Ṣé ẹ̀yin náà ní takisí ní ìlú yín?

Báyọ̀:: Bẹ́ẹ̀ni. Orúkọ ilé iṣẹ́ tó ni takisí ni a fi ń pe wọ́n, fún àpẹẹrẹ Eco Cab.

Tóyìn: Hmm. Gbogbo takisí jẹ́ nǹkan kan náà ní ìlú Èkó ní Nàìjíríyà, sùgbọ́n àwọn ènìyàn tún ń wọ Uber nísisìyí.

Báyọ̀: Uber náà wà ní ìlú Amẹ́ríkà.

Tóyìn: Ṣùgbọ́n n kò rò pé ẹ ń lo alùpùpù láti fi gbé àwọn ènìyàn

Báyọ̀: Ótì. Oníkálukú máa ń lo alùpùpù bíi nǹkan ìrìnna. Àwọn míràn tún máa ń lò ó fún fàájì.

Tóyìn: Ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìlú ni Nàìjíríyà, alùpùpù jẹ́ nǹkan ìrìnnà tí a máa ń lò ní àwọn  ọ̀nà tí kò fi bẹ́ẹ̀ dára.

Báyọ̀: Hmm, ó yé mi.

 

Practice: Interpersonal Communication

  • Read the transcript and practice a similar roleplay with your classmate

Grammar Notes

Prepositions

Prepositions are words that show the relationship between two nouns or pronouns in a sentence. The Yoruba language marks prepositions using different words, including ní “at or in,” sí “to,”  fún “for,” pẹ̀lú “with,” láti “from,” ní iwájú “in front of,”  ní ẹ̀gbẹ́ “beside,” ní ìdojúkọ “across” etc.

Examples:

  1. Mo jẹ ẹ̀wà pẹ̀lú búrẹ́dì.  “I ate beans with bread.”
  2. Olú dúró pẹ̀lú Títí. “Olú stood with Títí.”
  3. Mo maá wa ọkọ̀ mi fún wákàtí méjìdínlógún  láti Wisconsin dé Miami, Florida. “I will drive my car for eighteen hours from Wisconsin to Miami.”
  4. Mo máa lọ sí títì Agboawó ní ìlú Ìbàdàn “I will go to Agbowó road in Ìbàdàn”

When a preposition has more than one meaning, the context of use determines the best translation for such a preposition.

Examples:

5. Mo ra ọkọ̀ mi ní  ilé ìtajà Toyota. “I bought my car at the Toyota store.”

6. Mo ń gbé ní Madison. “I live in Madison.”

Other examples are:

7. Ilé bàbá mi wà ní iwájú títì Bodíjà ní Ibàdàn “My father’s house is in front of Bodija road in Ìbàdàn.”

8. Mo máa gbé kẹ̀kẹ́ mi si ẹ̀gbé títì ” I will put my bicycle beside the road ide.”

License

Yorùbá Dictionary Copyright © 2024 by Adeola Agoke. All Rights Reserved.

Share This Book