Housing and Community

Can Do Statement

  • Talking about houses, including types and designs
  • Talking about household objects as well as their location and uses
  • Talk about some houses in communities and neighborhoods

Vocabulary List

Click the audio icon below to play the recorded pronunciation for each word. You can also open the list below in a new tab, which can be downloaded or printed.

Practice: Interpretive Communication

Presentational Communication

Context: Tolú is talking about a house she will purchase in the future.

 

Transcript:

Bí ó tilẹ̀ je wípé n kìí se oníṣòwò  ilé ati ilẹ̀, mo fẹ́ràn láti kà nípa oríṣiríṣi ilé àti láti rí orísirísi ilé ńlá. Ní ọjọ́ iwájú mo fẹ́ ra ilé olókè méjì tí ó ní yàrá márùnún àti yàrá ìgbàlejò. Mo fẹ́ràn ilé ìdáná tí kò tóbi púpọ̀ ṣùgbọ́n tí ó lẹ́wà gan an ni. Bákan náà, mo fẹ́ kí ilé mi ní balùwẹ̀ mẹ́ta, yàrá ìgbafẹ́ , ibi ìjẹun, àti fàráńdà ńlá. Ilé mi kò ní ní àjà ilẹ̀ nítorí pé mo ń gbé ní Florida ṣùgbọ́n mo fẹ́ràn àjà ilẹ̀ gan an ni.

 

Practice: Presentational Communication

  • Using the transcript, find the words that describe a house
  • Click on the audio recording and restate them
  • Tell someone about your house.

Interpersonal Communication

Context: Báyọ̀: and Toyin are talking about their home countries and the differences in the houses they live in.

 

Transcript:

Tóyìn: Ilé bàbá mi wà ní ìlú Àkúrẹ́ ní Nàìjíríà. Ilé wa tóbi gan an.

Báyọ̀: Ṣé ilé pẹ̀tẹ́sì ni ilé yín ni?

Tóyìn: Rárá, ilé ilè ni.

Báyọ̀: Hàà, bàbá mi náà ní ilé ilè ní Amẹ́ríkà, ṣùgbọ́n mo fẹ́ràn àwọn ilé olókè bíi èyí. (Saheed points to some buildings outside)

Tóyìn: N kò bìkítà nípa ilé olókè rárá, nítorí pé ilé wa ní yàrá púpọ̀, ó tún ní fẹǹsì gíga àti àyè púpọ̀ láti ṣeré.

Báyọ̀: Mo fẹ́ràn pé ilé yín ní àyè púpọ̀ àti yàrá púpọ̀. Ilé tiwa kò ní fẹǹsì rárá.

Tóyìn: Kílódé?

Báyọ̀: Ní ilé Amẹ́ríkà, a kìí máa ń kọ́ féǹsì gíga, ṣùgbọ́n àwọn ilé míràn máa ń ní àjà ilẹ̀.

Tóyìn: Ó yé mi.  Fẹ́ǹsì kíkọ́ ṣe pàtàkì fún àwọn ilé ní ìlú mi.

 

Practice: Interpersonal Communication

  • Read the transcript
  • Formulate two questions about housing and ask your peer to respond to them. Switch roles.

Grammar Notes

Possessive pronouns.

Pronouns are a category of words that are used in place of a noun. Possessive pronouns, however, express ownership or possession. In such expressions, possessive pronouns indicate the owner of a particular item or thing, and this can be expressed thus:

Use of possessive pronouns in the first, second, and third persons,. In this instance, possessive pronouns function as noun qualifiers in the sentence.

Examples:

  1. Aṣọ mi nìyí. “This is my cloth.”
  2. Ilé yín wà ní ìdojúkọ títì Mọ́kọ́lá ní Ìbàdàn. “Your house is located across Mọkọ́lá road in Ìbàdàn.”
  3. Ọ̀rẹ́ wa  kò fẹ́ràn ìrẹsì jọ̀lọ́ọ̀fù. “Our friend does not like jollof rice.”
  4. Ọmọ wọn ń gbé ní àdúgbọ̀ wa. “Their child is livingin our neighborhood.”
  5. Ṣé aṣọ nìyí? “Is this your cloth?”

 

 

 

 

License

Yorùbá Dictionary Copyright © 2024 by Adeola Agoke. All Rights Reserved.

Share This Book