Road Transportation in Nigeria
Short Reading
Ní Nigeria, òkadà wúlò púpọ̀ láti tètè/sáré lọ sí ibikíbi tí o bá fẹ́ lọ láàrin ìlú. Ó yára ju takisí lọ nítorípé súnkẹrẹ fàkẹrẹ kìí sábàá mú ọ̀kadà; àtipé ọ̀kadà ni o máa ń rin awọn ojú ònà tí kò dára fún ọkọ̀. Ní awọn àdúgbò kan, Kẹ̀kẹ́ Marwa ni àwọn ènìyàn míran máa ń wọ̀, nítorípé wọ́n gbàgbọ́ pé ọ̀kadà léwu púpọ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ máa n pọ̀ láàrín ìlú, sì́bẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn máa ń wọ takisí tàbí bọ́ọ̀sì. Ní ìlú Èkó, Dáńfó ni bọ́ọ̀sì tí ó wọ́pọ̀ jùlọ.
Sùgbọ́n bí a bá fẹ́ rin ìrìnàjò ìlú kan sí òmíràn, ọkọ̀ ni a máa ń wọ̀. Oríṣiríṣi ọkọ̀ ni ó sì wà ṣugbọ́n bọ́ọ̀sì àti káà ni ó wọ́pọ̀ jù. Bí ó ti wù kí ọ̀nà jìn tó, ọkọ̀ ni ọ̀pọ̀ ènìyàn máa ń wọ.
Ní Nigeria, ètò ìrìnàjò ojú ọnà ni ó wọ́pọ̀ jù.
Vocabulary
1. wúlò – Useful
2. tètè/sáré – Quickly
3. ibikíbi – Anywhere
4. súnkẹrẹ fàkẹrẹ – Traffic
5. sábàá – Usually
6. ojú ònà – Road
7. léwu – Dangerous
8. sì́bẹ – still/yet
9. ìlú kan sí òmíràn – One town to another
10. wọ́pọ̀ jù – most common
11. ọkọ̀ – vehicle
12. káà – Car
13. ètò ìrìnàjò ojú ọnà – Road transportation system