Road Transportation in Nigeria

Short Reading

Ní Nigeria, òkadà wúlò púpọ̀ láti tètè/sáré lọ sí ibikíbi tí o bá fẹ́ lọ láàrin ìlú. Ó yára ju takisí lọ nítorípé súnkẹrẹ fàkẹrẹ kìí sábàá mú ọ̀kadà; àtipé ọ̀kadà ni o máa ń rin awọn ojú ònà tí kò dára fún ọkọ̀. Ní awọn àdúgbò kan, Kẹ̀kẹ́ Marwa ni àwọn ènìyàn míran máa ń wọ̀, nítorípé wọ́n gbàgbọ́ pé ọ̀kadà léwu púpọ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ máa n pọ̀ láàrín ìlú, sì́bẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn máa ń wọ takisí tàbí bọ́ọ̀sì. Ní ìlú Èkó, Dáńfó ni bọ́ọ̀sì tí ó wọ́pọ̀ jùlọ.

Sùgbọ́n bí a bá fẹ́ rin ìrìnàjò ìlú kan sí òmíràn, ọkọ̀ ni a máa ń wọ̀. Oríṣiríṣi ọkọ̀ ni ó sì wà ṣugbọ́n bọ́ọ̀sì àti káà ni ó wọ́pọ̀ jù. Bí ó ti wù kí ọ̀nà jìn tó, ọkọ̀ ni ọ̀pọ̀ ènìyàn máa ń wọ.

Ní Nigeria, ètò ìrìnàjò ojú ọnà ni ó wọ́pọ̀ jù.

 

Vocabulary

1. wúlò   –  Useful

2. tètè/sáré  –  Quickly

3. ibikíbi  –  Anywhere

4. súnkẹrẹ fàkẹrẹ  –  Traffic

5. sábàá  –  Usually

6. ojú ònà  –  Road

7.  léwu  –  Dangerous

8. sì́bẹ  –  still/yet

9. ìlú kan sí òmíràn  –  One town to another

10. wọ́pọ̀ jù  –  most common

11. ọkọ̀  –  vehicle

12. káà  –  Car

13. ètò ìrìnàjò ojú ọnà  –  Road transportation system


License

Materials for Yoruba Learners Copyright © by kdthomp3. All Rights Reserved.