Describing my Family
Short Reading
Tọ́lá talks about her family to a group of friends.
Ẹbí mi kéré. Mo ní bàbá. Mo ní màmá. Mo ní àbúrò ọkùnrin kan àti ẹ̀gbọ́n ọkùnrin kan. N kò ní ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò obìnrin kankan. Orúkọ bàbá mi ni Jíire. Orúkọ màmá mi ni Bísí. Orúkọ àbúrò mi ni Báyọ̀. Orúkọ ẹ̀gbọ́n mi ni Túndé. Tẹ́lẹ̀, gbogbo ẹbí mi ń gbé ní Ìbàdàn ní Nàìjíríà. Nísìsìnyì, ẹ̀gbọ́n mi ń gbé ní Èkó ni Nàìjíríà.
Reading Test